15. Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.
16. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣe afarawe mi.
17. Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo.
18. Ṣugbọn awọn ẹlomiran gberaga ninu nyin, bi ẹnipe emi kì yio tọ̀ nyin wá mọ́.
19. Ṣugbọn emi ó tọ̀ nyin wá ni lọ̃lọ yi, bi Oluwa ba fẹ; kì si iṣe ọ̀rọ awọn ti ngberaga li emi o mọ̀, bikoṣe agbara.