1. Kor 3:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e.

11. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.

12. Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, akekù koriko le ori ipilẹ yi;

13. Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe.

14. Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ̀ ba duro, on ó gbà ère.

15. Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja.

16. Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin?

1. Kor 3