8. Ṣugbọn emi o duro ni Efesu titi di Pẹntikọsti.
9. Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ.
10. Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe.
11. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin.
12. Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.
13. Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara.