1. Kor 16:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Mo yọ̀ fun wíwa Stefana ati Fortunatu ati Akaiku: nitori eyi ti o kù nipa tinyin nwọn ti fi kún u.

18. Nitoriti nwọn tù ẹmí mi lara ati tinyin: nitorina ẹ mã gbà irú awọn ti o ri bẹ̃.

19. Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn.

20. Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.

21. Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá.

22. Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata.

1. Kor 16