29. Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ.
30. Bi a bá si fi ohunkohun hàn ẹniti o joko nibẹ, jẹ ki ẹni iṣaju dakẹ.
31. Gbogbo nyin le mã sọtẹlẹ li ọkọ̃kan, ki gbogbo nyin le mã kọ ẹkọ ki a le tu gbogbo nyin ni inu.
32. Ẹmí awọn woli a si ma tẹriba fun awọn woli.
33. Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́.