16. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye.
17. Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai.
18. Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi.
19. Nwọn ti ọdọ wa jade, ṣugbọn nwọn ki iṣe ará wa; nitori nwọn iba ṣe ará wa, nwọn iba bá wa duro: ṣugbọn nwọn jade ki a le fi wọn hàn pe gbogbo nwọn ki iṣe ará wa.
20. Ṣugbọn ẹnyin ni ifororo-yan lati ọdọ Ẹni Mimọ́ nì wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo.