1. Joh 2:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNYIN ọmọ mi, iwe nkan wọnyi ni mo kọ si nyin, ki ẹ má bã dẹṣẹ̀. Bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ̀, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo:

2. On si ni ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa: kì si iṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araiye pẹlu.

3. Nipa eyi li a si mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba npa ofin rẹ̀ mọ́.

4. Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀.

5. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba npa ofin rẹ̀ mọ́, lara rẹ̀ li a gbé mu ifẹ Ọlọrun pé nitõtọ. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa mbẹ ninu rẹ̀,

6. Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rẹ̀, on na pẹlu si yẹ lati mã rìn gẹgẹ bi on ti rìn.

7. Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́.

8. Ẹ̀wẹ, ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, eyiti iṣe otitọ ninu rẹ̀ ati ninu nyin, nitori òkunkun nkọja lọ, imọlẹ otitọ si ti ntàn.

1. Joh 2