1. A. Ọba 6:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ.

8. Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta.

9. Bẹ̃li o kọ́ ile na, ti o si pari rẹ̀: o si fi gbelerù ati apako kedari bò ile na.

10. O si kọ́ yara gbè gbogbo ile na, igbọnwọ marun ni giga: o fi ìti kedari mú wọn fi ara ti ile na.

11. Ọ̀rọ Oluwa si tọ Solomoni wá wipe,

12. Nipa ti ile yi ti iwọ nkọ́ lọwọ nì, bi iwọ o ba rin ninu aṣẹ mi, ti iwọ o si ṣe idajọ mi, ati ti iwọ o si pa gbogbo ofin mi mọ lati ma rin ninu wọn, nigbana ni emi o mu ọ̀rọ mi ṣẹ pẹlu rẹ, ti mo ti sọ fun Dafidi, baba rẹ;

13. Emi o si ma gbe ãrin awọn ọmọ Israeli, emi kì o si kọ̀ Israeli, enia mi.

14. Solomoni si kọ́ ile na, o si pari rẹ̀.

15. O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na.

16. O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ.

17. Ati ile na, eyini ni Tempili niwaju rẹ̀, jẹ ogoji igbọnwọ ni gigùn.

18. Ati kedari ile na ninu ile li a fi irudi ati itanna ṣe iṣẹ ọnà rẹ̀: gbogbo rẹ̀ kiki igi kedari; a kò ri okuta kan.

1. A. Ọba 6