18. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò sọ fun ọ, pe on kì o fọ̀ ire si mi, bikoṣe ibi?
19. On si wipe, Nitorina, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun-ọrun duro li apa ọtun ati li apa òsi rẹ̀.
20. Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ki o le goke lọ, ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ẹnikan si wi bayi, ẹlomiran si sọ miran.
21. Ẹmi kan si jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a.
22. Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃.
23. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi-eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ.
24. Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana sunmọ ọ, o si lu Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ?
25. Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o lọ lati inu iyẹwu de iyẹwu lati fi ara rẹ pamọ.
26. Ọba Israeli si wipe, Mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba:
27. Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi: Ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi onjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia.