17. Omri si goke lati Gibbetoni lọ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, nwọn si do tì Tirsa.
18. O si ṣe, nigbati Simri mọ̀ pe a gba ilu, o wọ inu ãfin ile ọba lọ, o si tẹ iná bọ ile ọba lori ara rẹ̀, o si kú.
19. Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀.
20. Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
21. Nigbana li awọn enia Israeli da meji; apakan awọn enia ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin, lati fi i jọba, apakan si ntọ̀ Omri lẹhin.