1. A. Ọba 14:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Li àkoko na, Abijah ọmọ Jeroboamu ṣàisan.

2. Jeroboamu si wi fun aya rẹ̀ pe, Dide, emi bẹ̀ ọ, si pa ara rẹ dà, ki a má ba le mọ̀ ọ li aya Jeroboamu; ki o si lọ si Ṣilo: kiyesi i, nibẹ li Ahijah, woli wà, ti o sọ fun mi pe, emi o jọba lori enia yi.

3. Ki o si mu ìṣu àkara mẹwa li ọwọ́ rẹ, ati akara wẹwẹ, ati igo oyin, ki o si lọ sọdọ rẹ̀: on o si wi fun ọ bi yio ti ri fun ọmọde na.

4. Aya Jeroboamu si ṣe bẹ̃, o si dide, o si lọ si Ṣilo, o si wá si ile Ahijah. Ṣugbọn Ahijah kò riran; nitoriti oju rẹ̀ fọ́ nitori ogbó rẹ̀.

5. Oluwa si wi fun Ahijah, pe, Kiyesi i, aya Jeroboamu mbọ̀ wá bère ohun kan lọwọ rẹ niti ọmọ rẹ̀: nitori ti o ṣàisan: bayi bayi ni ki iwọ ki o wi fun u: yio si ṣe, nigbati o ba wọle, yio ṣe ara rẹ̀ bi ẹlomiran.

1. A. Ọba 14