21. O si kigbe si enia Ọlọrun ti o ti Juda wá wipe, bayi li Oluwa wi: Niwọn bi iwọ ti ṣe aigbọran si ẹnu Oluwa, ti iwọ kò si pa aṣẹ na mọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ pa fun ọ.
22. Ṣugbọn iwọ pada, iwọ si ti jẹ onjẹ, iwọ si ti mu omi ni ibi ti Oluwa sọ fun ọ pe, Máṣe jẹ onjẹ, ki o má si ṣe mu omi; okú rẹ kì yio wá sinu iboji awọn baba rẹ.
23. O si ṣe, lẹhin igbati o ti jẹ onjẹ, ati lẹhin igbati o ti mu, li o di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u, eyini ni, fun woli ti o ti mu pada bọ̀.