1. NIGBATI emi iba mu Israeli li ara dá, nigbana ni ẹ̀ṣẹ Efraimu fi ara hàn, ati ìwa-buburu Samaria; nitori nwọn ṣeké; olè si wọle, ọwọ́ olè si nkoni lode.
2. Nwọn kò si rò li ọkàn wọn pe, emi ranti gbogbo ìwa-buburu wọn: nisisiyi iṣẹ ara wọn duro yi wọn ka; nwọn wà niwaju mi.
3. Nwọn fi ìwa-buburu wọn mu ki ọba yọ̀; nwọn si fi eké wọn mu awọn ọmọ-alade yọ̀.
4. Gbogbo nwọn ni panṣagà, bi ãrò ti alakàra mu gboná, ti o dawọ́ kikoná duro, lẹhìn igbati o ti pò iyẹ̀fun tan, titi yio fi wú.
5. Li ọjọ ọba wa, awọn ọmọ-alade ti fi oru ọti-waini mu u ṣaisàn; o nà ọwọ́ rẹ̀ jade pẹlu awọn ẹlẹgàn.