8. Nwọn jẹ ẹ̀ṣẹ awọn enia mi, nwọn si gbe ọkàn wọn si aiṣedẽde wọn.
9. Yio si ṣe, gẹgẹ bi enia, bẹ̃li alufa: emi o si bẹ̀ wọn wò nitori ọ̀na wọn, emi o si san èrè iṣẹ wọn padà fun wọn.
10. Nwọn o si jẹ, nwọn kì o si yó: nwọn o ṣe agbère, nwọn kì o si rẹ̀: nitori nwọn ti fi ati-kiyesi Oluwa silẹ.
11. Agbère ati ọti-waini, ati ọti-waini titun a ma gbà enia li ọkàn.
12. Awọn enia mi mbère ìmọ lọwọ igi wọn, ọpá wọn si nfi hàn fun wọn: nitori ẹmi agbère ti mu wọn ṣìna, nwọn si ti ṣe agbère lọ kuro labẹ Ọlọrun wọn.
13. Nwọn rubọ lori awọn oke-nla, nwọn si sun turari lori awọn oke kékèké, labẹ igi oaku ati igi poplari ati igi ẹlmu, nitoriti ojìji wọn dara: nitorina awọn ọmọbinrin nyin yio ṣe agbère, ati awọn afẹ́sọnà nyin yio ṣe panṣagà.