Hos 12:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Aiṣedẽde mbẹ ni Gileadi bi? nitõtọ asan ni nwọn: nwọn rubọ akọ malu ni Gilgali; nitõtọ, pẹpẹ wọn dabi ebè ni aporo oko.

12. Jakobu si salọ si ilẹ Siria: Israeli si sìn nitori aya kan; ati nitori aya kan li o ṣọ agùtan.

13. Ati nipa woli kan ni Oluwa mu Israeli jade ni Egipti: nipa woli kan li a si pa on mọ.

14. Efraimu mu u binu kikorò: nitorina ni yio fi ẹjẹ̀ rẹ̀ si ori rẹ̀, ẹgàn rẹ̀ li Oluwa rẹ̀ yio si san padà fun u.

Hos 12