Hos 11:4-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo si ri si wọn bi awọn ti o mu ajàga kuro li ẹrẹkẹ wọn, mo si gbe onjẹ kalẹ niwaju wọn.

5. On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà.

6. Idà yio si ma gbe inu ilu rẹ̀, yio si run ìtikun rẹ̀, yio si jẹ wọn run, nitori ìmọran ara wọn.

7. Awọn enia mi si tẹ̀ si ifàsẹhin kuro lọdọ mi: bi o tilẹ̀ ṣepe nwọn pè wọn si Ọga-ogo jùlọ, nwọn kò jùmọ gbe e ga.

Hos 11