10. Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.
11. Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi.
12. Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa.
13. Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara,
14. Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye?