Heb 9:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ majẹmu iṣaju papa pẹlu ní ìlana ìsin, ati ibi mimọ́ ti aiye yi.

2. Nitoripe a pa agọ́ kan; eyi ti iṣaju ninu eyi ti ọpá fitila, ati tabili, ati akara ifihàn gbé wà, eyiti a npè ni ibi mimọ́.

3. Ati lẹhin aṣọ ikele keji, on ni agọ́ ti a npè ni ibi mimọ julọ;

4. Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu;

5. Ati lori rẹ̀ ni awọn kerubu ogo ti o ṣijibo ìtẹ́ ãnu; eyiti a kò le sọrọ rẹ̀ nisisiyi lọkọ̃kan.

6. Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin.

7. Ṣugbọn sinu ekeji ni olori alufa nikan imã lọ lẹ̃kanṣoṣo li ọdún, kì iṣe li aisi ẹ̀jẹ, ti on fi rubọ fun ara rẹ̀ na, ati fun ìṣina awọn enia:

Heb 9