1. NITORINA, ẹ jẹ ki a bẹ̀ru, bi a ti fi ileri ati wọ̀ inu isimi rẹ̀ silẹ fun wa, ki ẹnikẹni ninu nyin ki o má bã dabi ẹnipe o ti kùna rẹ̀.
2. Nitoripe a ti wasu ihinrere fun wa gẹgẹ bi fun awọn na, ṣugbọn ọ̀rọ ti nwọn gbọ́ kò ṣe wọn ni ire, nitoriti kò dàpọ mọ́ igbagbọ́ ninu awọn ti o gbọ́ ọ.
3. Nitoripe awa ti o ti gbagbọ́ wọ̀ inu isimi gẹgẹ bi o ti wi, Bi mo ti bura ninu ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi: bi o tilẹ ti ṣe pe a ti pari iṣẹ wọnni lati ipilẹ aiye.
4. Nitori o ti sọ nibikan niti ọjọ keje bayi pe, Ọlọrun si simi ni ijọ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo.
5. Ati nihinyi ẹ̀wẹ pe, Nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi.
6. Nitorina bi o ti jẹ pe, o kù ki awọn kan wọ̀ inu rẹ̀, ati awọn ti a ti wasu ihinrere nã fun niṣãju kò wọ inu rẹ̀ nitori aigbọran: