Hab 3:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ni irúnu ni iwọ rìn ilẹ na ja, ni ibinu ni iwọ ti tẹ̀ awọn orilẹ-ede rẹ́.

13. Iwọ jade lọ fun igbàla awọn enia rẹ, fun igbàla ẹni atororosi rẹ; iwọ ti ṣá awọn olori kuro ninu ile awọn enia buburu, ni fifi ipinlẹ hàn titi de ọrùn.

14. Iwọ ti fi ọ̀pa rẹ̀ lu awọn olori iletò rẹ̀ já: nwọn rọ́ jade bi ãjà lati tu mi ka: ayọ̀ wọn ni bi ati jẹ talakà run nikọ̀kọ.

15. Iwọ fi awọn ẹṣin rẹ rìn okun ja, okìti omi nla.

16. Nigbati mo gbọ́, ikùn mi warìri; etè mi gbọ̀n li ohùn na; ibàjẹ wọ̀ inu egungun mi lọ, mo si warìri ni inu mi, ki emi ba le simi li ọjọ ipọnju: nigbati o ba goke tọ̀ awọn enia lọ, yio ke wọn kuro.

17. Bi igi ọpọ̀tọ kì yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko kì yio si mu onje wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ́ ẹran kì yio si si ni ibùso mọ:

18. Ṣugbọn emi o ma yọ̀ ninu Oluwa, emi o ma yọ̀ ninu Ọlọrun igbàla mi.

19. Oluwa Ọlọrun ni agbara mi, on o si ṣe ẹsẹ̀ mi bi ẹsẹ̀ agbọ̀nrin, lori ibi giga mi ni yio si mu mi rìn. Si olori akọrin lara ohun-ọnà orin olokùn mi.

Hab 3