Hab 3:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ADURA Habakuku woli lara Sigionoti.

2. Oluwa, mo ti gbọ́ ohùn rẹ, ẹ̀ru si bà mi: Oluwa, mu iṣẹ rẹ sọji lãrin ọdun, lãrin ọdun sọ wọn di mimọ̀; ni ibinu ranti ãnu.

3. Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀.

4. Didán rẹ̀ si dabi imọlẹ; itanṣan nti iha rẹ̀ wá: nibẹ̀ si ni ipamọ agbara rẹ̀ wà.

5. Ajàkalẹ arùn nlọ niwaju rẹ̀, ati okunrun njade lati ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ.

6. O duro, o si wọ̀n ilẹ aiye: o wò, o si mu awọn orilẹ-ède warìri; a si tú awọn oke-nla aiyeraiye ká, awọn òkèkékèké aiyeraiye si tẹba: ọ̀na rẹ̀ aiyeraiye ni.

7. Mo ri agọ Kuṣani labẹ ipọnju: awọn aṣọ-ikele ilẹ̀ Midiani si warìri.

8. Oluwa ha binu si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si okun, ti iwọ fi ngùn ẹṣin rẹ ati kẹkẹ́ igbàla rẹ?

Hab 3