Hab 1:15-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Iwọ ni àwọn lati fi gbé gbogbo wọn, nwọn nfi àwọn mu wọn, nwọn si nfi awò wọn kó wọn: nitorina ni nwọn ṣe nyọ̀, ti inu wọn si ndùn.

16. Nitorina, nwọn nrubọ si àwọn wọn, nwọn si nsùn turari fun awò wọn; nitori nipa wọn ni ipin wọn ṣe li ọrá, ti onjẹ wọn si fi di pupọ̀.

17. Nitorina, nwọn o ha ma dà àwọn wọn, nwọn kì yio ha dẹkun lati ma fọ́ orilẹ-ède gbogbo?

Hab 1