26. O si wipe, Olubukun li OLUWA Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio ma ṣe iranṣẹ rẹ̀.
27. Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ́ Ṣemu; Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn.
28. Noa si wà ni irinwo ọdun o din ãdọta, lẹhin ìkún-omi.
29. Gbogbo ọjọ́ Noa jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí ãdọta: o si kú.