Gẹn 9:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Yio si ṣe, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òṣumare na li awọsanma:

15. Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹnyin, ati gbogbo ọkàn alãye ni gbogbo ẹdá; omi ki yio si di kíkun mọ́ lati pa gbogbo ẹdá run.

16. Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye.

17. Ọlọrun si wi fun Noa pe, Eyiyi li àmi majẹmu na, ti mo ba ara mi ati ẹdá gbogbo ti o wà lori ilẹ dá.

18. Awọn ọmọ Noa, ti o si jade ninu ọkọ̀ ni Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti: Hamu si ni baba Kenaani.

19. Awọn mẹta wọnyi li ọmọ Noa: lati ọdọ wọn li a gbé ti tàn ká gbogbo aiye.

20. Noa si bẹ̀rẹ si iṣe àgbẹ, o si gbìn ọgbà-àjara:

21. O si mu ninu ọti-waini na, o mu amupara; o si tú ara rẹ̀ si ìhoho ninu agọ́ rẹ̀.

22. Hamu, baba Kenaani, si ri ìhoho baba rẹ̀, o si sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ meji lode.

Gẹn 9