17. Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u.
18. Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ pẹlu, nwọn wolẹ niwaju rẹ̀: nwọn si wipe, Wò o, iranṣẹ rẹ li awa iṣe.
19. Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun?
20. Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là.
21. Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.