Gẹn 5:13-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Kenani si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ogoji lẹhin ti o bí Mahalaleli, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

14. Gbogbo ọjọ́ Kenani si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé mẹwa: o si kú.

15. Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi:

16. Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

17. Gbogbo ọjọ́ Mahalaleli si jẹ ẹ̃dẹgbẹ̀run ọdún o dí marun: o si kú.

18. Jaredi si wà li ọgọjọ ọdún o lé meji, o si bí Enoku:

19. Jaredi si wà li ẹgbẹrin ọdún lẹhin igbati o bì Enoku, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

20. Gbogbo ọjọ́ Jaredi si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mejidilogoji: o si kú.

21. Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela:

22. Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

23. Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji:

24. Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ.

25. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki:

Gẹn 5