Gẹn 47:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Josefu si wipe, Ẹ mú ẹran nyin wá, emi o si fun nyin li onjẹ dipò ẹran nyin, bi owo ba tán.

17. Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na.

18. Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa:

19. Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro.

20. Bẹ̃ni Josefu rà gbogbo ilẹ Egipti fun Farao; nitori olukuluku awọn ara Egipti li o tà oko rẹ̀, nitori ti ìyan na mú wọn: ilẹ si di ti Farao.

21. Bi o si ṣe ti awọn enia ni, o ṣí wọn si ilu, lati opin ilẹ kan ni Egipti dé opin ilẹ keji.

22. Kìki ilẹ awọn alufa ni kò rà; nitori ti awọn alufa ní ipín ti wọn lati ọwọ́ Farao wá, nwọn si njẹ ipín wọn ti Farao fi fun wọn; nitorina ni nwọn kò fi tà ilẹ wọn.

23. Nigbana ni Josefu wi fun awọn enia pe, Kiyesi i, emi ti rà nyin loni ati ilẹ nyin fun Farao: wò o, irugbìn niyi fun nyin, ki ẹnyin ki o si gbìn ilẹ na.

Gẹn 47