Gẹn 46:32-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Oluṣọ-agutan si li awọn ọkunrin na, ẹran sisìn ni iṣẹ wọn; nwọn si dà agbo-ẹran ati ọwọ́-ẹran wọn wá, ati ohun gbogbo ti nwọn ní.

33. Yio si ṣe, nigbati Farao ba pè nyin, ti yio si bi nyin pe, Kini iṣẹ nyin?

34. Ki ẹnyin ki o wipe, Òwo awọn iranṣẹ rẹ li ẹran sisìn lati ìgba ewe wa wá titi o fi di isisiyi, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu: ki ẹnyin ki o le joko ni ilẹ Goṣeni; nitori irira li oluṣọ-agutan gbogbo si awọn ara Egipti.

Gẹn 46