16. Ati awọn ọmọ Gadi; Sifioni, ati Haggi, Ṣuni, ati Esboni, Eri, ati Arodi, ati Areli.
17. Ati awọn ọmọ Aṣeri; Jimna, ati Iṣua, ati Isui, ati Beria, ati Sera arabinrin wọn: ati awọn ọmọ Beria; Heberi, ati Malkieli.
18. Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun.
19. Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini.
20. Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u.