3. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi ni Josefu; baba mi wà sibẹ̀? awọn arakunrin rẹ̀ kò si le da a lohùn; nitori ti ẹ̀ru bà wọn niwaju rẹ̀.
4. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti.
5. Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là.