Gẹn 43:9-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Emi ni yio ṣe onigbọwọ rẹ̀: li ọwọ́ mi ni iwọ o bère rẹ̀; bi emi kò ba mú u pada fun ọ wá, ki nsi mu u duro niwaju rẹ, njẹ emi ni yio rù ẹbi na lailai.

10. Bikoṣepe bi awa ti nṣe ilọra, awa iba sa ti pada bọ̀ lẹrinkeji nisisiyi.

11. Israeli baba wọn si wi fun wọn pe, Njẹ bi bẹ̃ ba ni, eyi ni ki ẹ ṣe, ẹ mú ninu ãyo eso ilẹ yi, sinu ohun-èlo nyin, ki ẹ si mú ọrẹ lọ fun ọkunrin na, ikunra diẹ, ati oyin diẹ, ati turari, ojia, eso pupa, ati eso almondi:

12. Ki ẹ si mú owo miran li ọwọ́ nyin; ati owo ti a mú pada wá li ẹnu àpo nyin, ẹ si tun mú u li ọwọ́ lọ; bọya o le ṣe èṣi:

13. Ẹ mú arakunrin nyin pẹlu, ẹ si dide, ẹ tun pada tọ̀ ọkunrin na lọ:

14. Ki Ọlọrun Olodumare ki o si fun nyin li ãnu niwaju ọkunrin na, ki o le rán arakunrin nyin ọhún wá, ati Benjamini. Bi a ba gbà mi li ọmọ, a gbà mi li ọmọ.

15. Awọn ọkunrin na si mú ọrẹ na, nwọn si mú iṣẹ́po owo meji li ọwọ́ wọn, ati Benjamini; nwọn si dide, nwọn si sọkalẹ lọ si Egipti, nwọn si duro niwaju Josefu.

16. Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri.

17. Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu.

18. Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa.

19. Nwọn si sunmọ iriju ile Josefu, nwọn si bá a sọ̀rọ li ẹnu-ọ̀na ile na,

20. Nwọn si wipe, Alagba, nitõtọ li awa sọkalẹ wá ni iṣaju lati rà onjẹ:

21. O si ṣe, nigbati awa dé ile-èro, ti awa tú àpo wa, si kiyesi i, owo olukuluku wà li ẹnu àpo rẹ̀, owo wa ni pípe ṣánṣan: awa si tun mú u li ọwọ́ pada wá.

Gẹn 43