Israeli baba wọn si wi fun wọn pe, Njẹ bi bẹ̃ ba ni, eyi ni ki ẹ ṣe, ẹ mú ninu ãyo eso ilẹ yi, sinu ohun-èlo nyin, ki ẹ si mú ọrẹ lọ fun ọkunrin na, ikunra diẹ, ati oyin diẹ, ati turari, ojia, eso pupa, ati eso almondi: