6. Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ.
7. Josefu si ri awọn arakunrin rẹ̀, o si mọ̀ wọn, ṣugbọn o fi ara rẹ̀ ṣe àjeji fun wọn, o si sọ̀rọ akọ si wọn: o si wi fun wọn pe, Nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, Lati ilẹ Kenaani lati rà onjẹ.
8. Josefu si mọ̀ awọn arakunrin rẹ̀, ṣugbọn awọn kò mọ̀ ọ.
9. Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá.