Gẹn 42:27-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀.

28. O si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Nwọn mú owo mi pada; si wò o, o tilẹ wà li àpo mi: àiya si fò wọn, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Kili eyiti Ọlọrun ṣe si wa yi?

29. Nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti o bá wọn fun u wipe,

30. Ọkunrin na ti iṣe oluwa ilẹ na, sọ̀rọ lile si wa, o si fi wa pè amí ilẹ na.

31. A si wi fun u pe, Olõtọ, enia li awa; awa ki iṣe amí:

32. Arakunrin mejila li awa, ọmọ baba wa; ọkan kò sí, abikẹhin si wà lọdọ baba wa ni ilẹ Kenaani loni-oloni.

33. Ọkunrin na, oluwa ilẹ na, si wi fun wa pe, Nipa eyi li emi o fi mọ̀ pe olõtọ enia li ẹnyin; ẹ fi ọkan ninu awọn arakunrin nyin silẹ lọdọ mi, ki ẹ si mú onjẹ nitori ìyan ile nyin, ki ẹ si ma lọ.

34. Ẹ si mú arakunrin nyin abikẹhin nì tọ̀ mi wá: nigbana li emi o mọ̀ pe ẹnyin ki iṣe amí, bikoṣe olõtọ enia: emi o si fi arakunrin nyin lé nyin lọwọ, ẹnyin o si ma ṣòwo ni ilẹ yi.

35. O si ṣe, bi nwọn ti ndà àpo wọn, wò o, ìdi owo olukuluku wà ninu àpo rẹ̀: nigbati awọn ati baba wọn si ri ìdi owo wọnni, ẹ̀ru bà wọn.

Gẹn 42