Gẹn 41:30-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ;

31. A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi.

32. Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan.

33. Njẹ nisisiyi, ki Farao ki o wò amoye ati ọlọgbọ́n ọkunrin kan, ki o si fi i ṣe olori ilẹ Egipti.

34. Ki Farao ki o ṣe eyi, ki o si yàn awọn alabojuto si ilẹ yi, ki nwọn ki o si gbà idamarun ni ilẹ Egipti li ọdún meje ọ̀pọ nì.

35. Ki nwọn ki o si kó gbogbo onjẹ ọdún meje rere nì ti o dé, ki nwọn ki o si tò ọkà jọ si ọwọ́ Farao, ki nwọn ki o si pa onjẹ mọ́ ni ilu wọnni.

36. Onjẹ na ni yio si ṣe isigbẹ fun ilẹ dè ọdún meje ìyan na, ti mbọ̀wá si ilẹ Egipti; ki ilẹ ki o má ba run nitori ìyan na.

37. Ohun na si dara li oju Farao, ati li oju gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.

38. Farao si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A ha le ri ẹnikan bi irú eyi, ọkunrin ti Ẹmi Ọlọrun mbẹ ninu rẹ̀?

39. Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ:

40. Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ:

41. Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.

Gẹn 41