Gẹn 38:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. A si wi fun Tamari pe, Kiyesi i, baba ọkọ rẹ lọ si Timnati lati rẹrun agutan rẹ̀.

14. O si bọ́ aṣọ opó rẹ̀ kuro li ara rẹ̀, o si fi iboju bò ara rẹ̀, o si roṣọ, o si joko li ẹnubode Enaimu, ti o wà li ọ̀na Timnati; nitoriti o ri pe Ṣela dàgba, a kò si fi on fun u li aya.

15. Nigbati Judah ri i, o fi i pè panṣaga; nitori o boju rẹ̀.

16. O si yà tọ̀ ọ li ẹba ọ̀na, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, wá na, jẹ ki emi ki o wọle tọ̀ ọ; (on kò sa mọ̀ pe aya ọmọ on ni iṣe.) On si wipe Kini iwọ o fi fun mi, ki iwọ ki o le wọle tọ̀ mi?

17. O si wipe, emi o rán ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. On si wipe, iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi rán a wá?

18. O si bi i pe, Ògo kili emi o fi fun ọ? on si wipe, Èdidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpá rẹ ti o wà li ọwọ́ rẹ; o si fi wọn fun u, o si wọle tọ̀ ọ lọ, on si ti ipa ọdọ rẹ̀ yún.

Gẹn 38