12. Nigbati ọjọ́ si npẹ́, ọmọbinrin Ṣua, aya Juda kú; Judah si gbipẹ̀, o si tọ̀ awọn olurẹrun agutan rẹ̀, lọ si Timnati, on ati Hira ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu.
13. A si wi fun Tamari pe, Kiyesi i, baba ọkọ rẹ lọ si Timnati lati rẹrun agutan rẹ̀.
14. O si bọ́ aṣọ opó rẹ̀ kuro li ara rẹ̀, o si fi iboju bò ara rẹ̀, o si roṣọ, o si joko li ẹnubode Enaimu, ti o wà li ọ̀na Timnati; nitoriti o ri pe Ṣela dàgba, a kò si fi on fun u li aya.
15. Nigbati Judah ri i, o fi i pè panṣaga; nitori o boju rẹ̀.