Gẹn 36:27-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani.

28. Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani.

29. Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori,

30. Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.

31. Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli.

32. Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba.

33. Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.

34. Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀.

Gẹn 36