5. Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu.
6. Bẹ̃ni Jakobu si wá si Lusi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, eyinì ni Beteli, on ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀.
7. O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni El-bet-el: nitori pe nibẹ̀ li Ọlọrun tọ̀ ọ wá, nigbati o sá kuro niwaju arakunrin rẹ̀.
8. Ṣugbọn Debora olutọ́ Rebeka kú, a si sin i nisalẹ Beteli labẹ igi oaku kan: orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Alloni-bakutu.
9. Ọlọrun si tún farahàn Jakobu, nigbati o ti Padan-aramu bọ̀, o si sure fun u.