Gẹn 35:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli.

11. Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá;

12. Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun.

13. Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ.

14. Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀.

15. Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.

16. Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u.

17. O si ṣe nigbati o wà ninu irọbí, ni iyãgba wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu.

18. O si ṣe, bi ọkàn rẹ̀ ti nlọ̀ (o sa kú) o sọ orukọ rẹ̀ ni Ben-oni: ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ ni Benjamini.

Gẹn 35