1. ỌLỌRUN si wi fun Jakobu pe, Dide goke lọ si Beteli ki o si joko nibẹ̀, ki o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, fun Ọlọrun, ti o farahàn ọ, nigbati iwọ sá kuro niwaju Esau, arakunrin rẹ.
2. Nigbana ni Jakobu wi fun awọn ara ile rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ti o wà li ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mú àjeji oriṣa ti o wà lọwọ nyin kuro, ki ẹnyin ki o si sọ ara nyin di mimọ́, ki ẹnyin ki o si pa aṣọ nyin dà:
3. Ẹ si jẹ ki a dide, ki a si goke lọ si Beteli; nibẹ̀ li emi o si gbé tẹ́ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ti o da mi li ohùn li ọjọ́ ipọnju mi, ẹniti o si wà pẹlu mi li àjo ti mo rè.
4. Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu.