Gẹn 34:5-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Jakobu si gbọ́ pe o ti bà Dina ọmọbinrin on jẹ́; njẹ awọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu awọn ẹran ni pápa: Jakobu si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ titi nwọn fi dé.

6. Hamori, baba Ṣekemu, si jade tọ̀ Jakobu lọ lati bá a sọ̀rọ.

7. Awọn ọmọ Jakobu si ti oko dé nigbati nwọn gbọ́: inu awọn ọkunrin na si bàjẹ́, inu si ru wọn gidigidi, nitori ti o ṣe ohun buburu ni Israeli, niti o bá ọmọbinrin Jakobu dàpọ: ohun ti a ki ba ti ṣe.

8. Hamori si bá wọn sọ̀rọ pe, Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, nfẹ́ ọmọbinrin nyin; emi bẹ̀ nyin, ẹ fi i fun u li aya.

9. Ki ẹnyin ki o si bá wa gbeyawo, ki ẹnyin ki o si fi awọn ọmọbinrin nyin fun wa, ki ẹnyin ki o si ma mú awọn ọmọbinrin wa.

10. Ẹnyin o si ma bá wa gbé: ilẹ yio si wà niwaju nyin, ẹnyin o joko ki ẹ si ma ṣòwo ninu rẹ̀, ki ẹ si ma ní iní ninu rẹ̀.

11. Ṣekemu si wi fun baba omidan na ati fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju nyin, ohun ti ẹnyin o si kà fun mi li emi o fi fun nyin.

12. Ẹ bère ana lọwọ mi ati ẹ̀bun bi o ti wù ki o pọ̀ to, emi o si fi fun nyin gẹgẹ bi ẹnyin o ti kà fun mi: ṣugbọn ẹ fun mi li omidan na li aya.

13. Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́:

14. Nwọn si wi fun wọn pe, Awa kò le ṣe nkan yi lati fi arabinrin wa fun ẹni alaikọlà, nitori ohun àbuku ni fun wa;

15. Kiki ninu eyi li awa le jẹ fun nyin: bi ẹnyin o ba wà bi awa, pe ki a kọ olukuluku ọkunrin nyin li ilà.

16. Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna.

17. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti wa lati kọlà; njẹ awa o mú ọmọbinrin wa, awa o si ba ti wa lọ.

18. Ọ̀rọ wọn si dún mọ́ Hamori, ati Ṣekemu, ọmọ Hamori.

19. Ọdọmọkunrin na kò si pẹ́ titi lati ṣe nkan na, nitoriti o fẹ́ ọmọbinrin Jakobu; o si li ọlá jù gbogbo ara ile baba rẹ̀ lọ.

20. Ati Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wá si ẹnubode ilu wọn, nwọn si bá awọn ara ilu wọn sọ̀rọ wipe,

21. Awọn ọkunrin wọnyi mbá wa gbé li alafia; nitorina ẹ jẹ ki nwọn ki o ma gbé ilẹ yi, ki nwọn ki o si ma ṣòwo nibẹ̀; kiyesi i, ilẹ sa gbàye tó niwaju wọn; ẹnyin jẹ ki a ma fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, ki awa ki o si ma fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn.

Gẹn 34