7. Ati Lea pẹlu ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba: nikẹhin ni Josefu ati Rakeli si sunmọ ọdọ rẹ̀, nwọn si tẹriba.
8. O si wipe, Kini iwọ fi ọwọ́ ti mo pade ni pè? On si wipe, Lati fi ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi ni.
9. Esau si wipe, Emi ní tó, arakunrin mi; pa eyiti o ní mọ́ fun ara rẹ.
10. Jakobu si wipe, Bẹ̃kọ, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi, njẹ gbà ọrẹ mi lọwọ mi: nitori ti emi sa ri oju rẹ bi ẹnipe emi ri oju Ọlọrun, ti inu rẹ si dùn si mi;
11. Emi bẹ̀ ọ, gbà ẹ̀bun mi ti a mú fun ọ wá; nitori ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ ba mi ṣe, ati pe, nitori ti mo ní tó. O si rọ̀ ọ, on si gbà a.
12. O si wipe, Jẹ ki a bọ́ si ọ̀na ìrin wa, ki a si ma lọ, emi o si ṣaju rẹ.
13. Ṣugbọn on wi fun u pe, oluwa mi mọ̀ pe awọn ọmọ kò lera, ati awọn agbo-ẹran, ati ọwọ́-malu ati awọn ọmọ wọn wà pẹlu mi: bi enia ba si dà wọn li àdaju li ọjọ́ kan, gbogbo agbo ni yio kú.
14. Emi bẹ̀ ọ, ki oluwa mi ki o ma kọja nṣó niwaju iranṣẹ rẹ̀: emi o si ma fà wá pẹlẹ, gẹgẹ bi awọn ẹran ti o saju mi, ati bi ara awọn ọmọ ti le gbà, titi emi o fi dé ọdọ oluwa mi ni Seiri.
15. Esau si wipe, Njẹ ki emi ki o fi enia diẹ silẹ pẹlu rẹ ninu awọn enia ti o pẹlu mi. On si wipe, Nibo li eyini jasi, ki emi ki o sa ri õre-ọfẹ li oju oluwa mi.
16. Esau si pada li ọjọ́ na li ọ̀na rẹ̀ lọ si Seiri.
17. Jakobu si rìn lọ si Sukkotu, o si kọ́ ile fun ara rẹ̀, o si pa agọ́ fun awọn ẹran rẹ̀: nitorina li a ṣe sọ orukọ ibẹ̀ na ni Sukkotu.
18. Jakobu si wá li alafia, si ilu Ṣekemu ti o wà ni ilẹ Kenaani, nigbati o ti Padan-aramu dé: o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ilu na.