24. O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ.
25. Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi.
26. O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi.
27. O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu.
28. O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori.
29. Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀.
30. Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si.