11. Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ.
12. Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ.
13. O si sùn nibẹ̀ li alẹ ijọ́ na; o si mú ninu ohun ti o tẹ̀ ẹ li ọwọ li ọrẹ fun Esau, arakunrin rẹ̀;
14. Igba ewurẹ, on ogún obukọ, igba agutan, on ogún àgbo,
15. Ọgbọ̀n ibakasiẹ ti o ní wàra, pẹlu awọn ọmọ wọn, ogojì abo-malu on akọ-malu mẹwa, ogún abo-kẹtẹkẹtẹ, on ọmọ-kẹtẹkẹtẹ mẹwa.