Gẹn 31:35-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na.

36. Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃?

37. Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji.

38. Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ.

39. Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru.

40. Bayi ni mo wà; ongbẹ ngbẹ mi li ọsán, otutù si nmu mi li oru: orun mi si dá kuro li oju mi.

41. Bayi li o ri fun mi li ogún ọdún ni ile rẹ; mo sìn ọ li ọdún mẹrinla nitori awọn ọmọbinrin rẹ mejeji, ati li ọdún mẹfa nitori ohun-ọ̀sin rẹ: iwọ si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa.

Gẹn 31