4. Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá.
5. O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ.
6. O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran.
7. O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn.