Gẹn 29:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn.

2. O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na.

3. Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀.

4. Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá.

5. O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ.

6. O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran.

Gẹn 29