5. Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau.
6. Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani;
7. Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu:
8. Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀;
9. Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.
10. Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani.
11. O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na.
12. O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.
13. Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ.
14. Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye.