19. Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi.
20. Isaaki si wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Ẽti ri ti iwọ fi tete ri i bẹ̃, ọmọ mi? on si wipe, Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u tọ̀ mi wá ni.
21. Isaaki si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, sunmọ mi, ki emi ki o fọwọbà ọ, ọmọ mi, bi iwọ iṣe Esau, ọmọ mi nitotọ, bi bẹ̃kọ.
22. Jakobu si sunmọ Isaaki baba rẹ̀, o si fọwọbà a, o si wipe, Ohùn Jakobu li ohùn, ṣugbọn ọwọ́ li ọwọ́ Esau.
23. On kò si mọ̀ ọ, nitoriti ọwọ́ rẹ̀ ṣe onirun, bi ọwọ́ Esau, arakunrin rẹ̀: bẹ̃li o sure fun u.
24. O si wipe, Iwọ ni Esau ọmọ mi nitotọ? o si wipe, emi ni.
25. O si wipe, Gbé e sunmọ ọdọ mi, emi o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ mi, ki ọkàn mi ki o le sure fun ọ. O si gbé e sunmọ ọdọ rẹ̀, o si jẹ: o si gbé ọti-waini fun u, on si mu.
26. Isaaki baba rẹ̀ si wi fun u pe, Sunmọ ihín nisisiyi ọmọ mi, ki o si fi ẹnu kò mi li ẹnu.
27. O si sunmọ ọ, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: o si gbọ́ õrùn aṣọ rẹ̀, o si sure fun u, o si wipe, Wò o, õrùn ọmọ mi o dabi õrùn oko eyiti OLUWA ti busi.
28. Ọlọrun yio si fun ọ ninu ìri ọrun, ati ninu ọrá ilẹ, ati ọ̀pọlọpọ ọkà ati ọti-waini:
29. Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ.
30. O si ṣe, bi Isaaki ti pari ire isú fun Jakobu, ti Jakobu si fẹrẹ má jade tan kuro niwaju Isaaki baba rẹ̀, ni Esau, arakunrin rẹ̀ wọle de lati igbẹ́ ọdẹ rẹ̀ wá.